SISAWARI EBUN TAWON OMO TO NI IPENIJA ARA NI

Written by on September 25, 2019

Won ti ro awon obi ti omo won ni awon ipenija lati tete sawari ebun tawon omo bee ba ni ki won le ranwon lowo.

Akowe Agba Ajo to nrisi oro awon odo nipinle Eko, Arabinrin Yewande Falugba lo soro amoran naa nibi idanileko olojo meji to waye fawon omo ileewe ijoba nipinle Eko.

Arabinrin Falugba salaye pe, yatosi riran omo to ni ipenija losileewe, idije opolo tun maa nran won lowo lati nigboya, to fi mo jijeki won kopa ninu ere idaraya to maa fun won lanfani lati fararora pelawon elegbe won.

O ro awon obi to lomo to nipenija eya ara lati mase foju rena won wipe won ko le wulo dipo bee, ki won ranwon  lowo sagbelaruge ebun ti won ni.

Arabinrin Falugba ro awon obi ati alagbato lati lo fi oruko eyikeyi omo won to ba nipenija ara sile lodo ajo to nrisoro awon omo bee nipinle Eko, kijoba le seto gidi fun won.


Reader's opinions

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *Current track

Title

Artist

Background